audio
audioduration (s)
2.7
7.15
user_id
stringclasses
2 values
transcript
stringlengths
39
86
00001-00250-99bbb30c
Nàìjíríà yóò gba ikọ̀ ọmọ ogun tuntun.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n fẹ́ gbógun ti ìdúnkòkò àti ètò ààbò tó ń ṣe sége-sège.
00001-00250-99bbb30c
Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Òṣínbàjò jẹ́ igbákejì ààrẹ.
00001-00250-99bbb30c
Mo lọ sí ìlú Àbújá lọ́jọ́ Ajé láti pàdé ọ̀rẹ́ mi.
00001-00250-99bbb30c
Mò ń gbọ́ orin nígbà tí mò ń lọ sílé ìjọsìn.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n lọ sí ìlà oòrùn láti kojú ikọ̀ ọlọtẹ̀.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n ya owó kan sọ́tọ̀ láti fi ra irinṣẹ́ ogun.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n ṣe àmójútó ètò ààbò lórílẹ̀ èdè yìí.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èèyàn àlááfíà.
00001-00250-99bbb30c
A ò ní fowó kún ọkọ̀ ojú irin nítorí àwọn mẹ̀kúnnù.
00001-00250-99bbb30c
Ìjọba kò ní dẹ́kun àti ṣèrànwọ́ nípa fífi owó kún ọkọ̀ ojú irin.
00001-00250-99bbb30c
Ó sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń bá àwọn akọ̀rọ̀yìn sọrọ̀.
00001-00250-99bbb30c
Lágbàáyé kò sí ibi tí wọ́n ti ń lo ọkọ̀ ojú irin láti pa owó sápò ìjọba.
00001-00250-99bbb30c
Ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó ọkọ̀ ojú irin yóò tún pèsè àwọn ọkọ̀ ojú irin tuntun.
00001-00250-99bbb30c
Olùdarí ò fèsì lórí ìgbà tí ọkọ̀ ojú irin láti Èkó sí Ìbàdàn yóò parí.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n sọ fún wa pé wọn yóò parí isẹ́ náà ní osú kẹrin, ọdún tó kọjá
00001-00250-99bbb30c
Wọn kò tí ì rí ẹrù wọn gbà ní èbúté láti ọ̀sẹ̀ to kọjá.
00001-00250-99bbb30c
Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà yóò tọwọ́bọ ìwé àdéhùn.
00001-00250-99bbb30c
Gbogbo owó tí wọ́n kó sálọ sí ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n dá padà.
00001-00250-99bbb30c
Ìpàdé ọ̀hún máa ń wáyé ní ọjọ́ Àìkú lọ́dọọdún.
00001-00250-99bbb30c
Olùdámọ̀ràn fún ìjọba lórí ètò ààbò sọ̀rọ̀ lórí àjálù inú àwùjọ.
00001-00250-99bbb30c
Aláṣẹ pàsẹ láti mú àwọn adarí agbègbè lọ sí ibi ìpéjọpọ̀ kan
00001-00250-99bbb30c
Ẹ̀mí tó sọnù ti di méjìlélógún báyìí, bi ìwà ìpànìyàn se ń tẹ̀síwájú.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ omíyalé tó ìjọba léti láti wá àtúnṣe sí i.
00001-00250-99bbb30c
Ó wá fi àìdùnnú rẹ̀ hàn lori ọwọ́ tí àwọn ọlọ́pàá fi mú ìsẹ̀lẹ̀ náà.
00001-00250-99bbb30c
Èèyàn márùn-ún farapa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá àti ilé sì jóná.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n ka ìwé òfin sí etí àwọn tó bá fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀.
00001-00250-99bbb30c
Títí tí wọn yóò fi mú àwọn afurasí náà àárín yín ni ọ̀daràn wà.
00001-00250-99bbb30c
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wà níbi ìpàdé ọ̀hún nígbà tí a bẹ̀rẹ̀.
00001-00250-99bbb30c
Ó wá kìlọ̀ kí wọ́n má gba ìwà ọ̀daràn láàyè ní agbègbè wọn.
00001-00250-99bbb30c
Àwọn ọ̀daràn wá ṣe ọṣẹ́ ní agbègbè ọ̀hún ní àsálẹ́ ọjọ́ Àìkú.
00001-00250-99bbb30c
Ìjàm̀bá iná ṣẹlẹ̀ ní ọjà Balógun nílùú Èkó.
00001-00250-99bbb30c
Ìjàm̀bá iná ń sẹlẹ lọ́wọ́-lọ́wọ́ lọ́jà Balógun nílùú Èkó
00001-00250-99bbb30c
Àwọn ọlọ́jà ti pàdánù ọ̀kẹ́ àìmọye dúkìá wọn.
00001-00250-99bbb30c
Àwọn agbébọn pa ènìyàn mẹ́tàlá nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n ṣe ìdájọ́ fún àwọn tó ṣe iṣẹ́ ibi náà.
05251-05500-PB050cdf
Ààrẹ sọ pé kò sí ànfààní níbi ẹ̀san, ìkórìíra àti ìwà ìbàjẹ́
00001-00250-99bbb30c
Ààrẹ rọ àwọn ọ̀dọ́ kí wọ́n máa gbé pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ àlááfíà.
00001-00250-99bbb30c
Nàìjíríà yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ lórí ètò ẹ̀kọ́ fún Éṣíà.
00001-00250-99bbb30c
Kí ìbáṣepọ̀ orílẹ̀ èdè méjéèjì náà tún lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí i.
00001-00250-99bbb30c
Akọ̀wé ìjọba àjọ tó ń mójútó ètò ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìbáṣepọ̀ yìí.
00001-00250-99bbb30c
Àǹfààní ńlá ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ náà yóò jẹ́ fún àwọn méjèèjì.
00001-00250-99bbb30c
Akútọ́ọ́lọ́ ló rán wọn láti béèrè ọ̀nà tí ìjọba ó fi ṣèrànwọ́
00001-00250-99bbb30c
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ló ṣàgbéyẹ̀wò ètò ààbò, òfin epo rọ̀bì.
00001-00250-99bbb30c
Ní kété tí wọ́n bá ti wọlé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ni iṣẹ́ bẹ̀rè.
00001-00250-99bbb30c
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní láti mójútó àwọn ìpele ìjọba yòókù.
00001-00250-99bbb30c
Ìjọba ń ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn tó fẹ́ ibùdó omi òkun.
00001-00250-99bbb30c
Ìjọba àpapọ̀ yóò sàtìlẹyìn níbi iṣẹ́ ọ̀nà márosẹ̀ náà.
00001-00250-99bbb30c
Gómìnà náà sọ pé isẹ́ àkànṣe méjì ní ìjọba ọ̀ún tí gùnlé.
00001-00250-99bbb30c
Mo gbóríyìn fún ààrẹ Bùhárí fún ètò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè.
05251-05500-PB050cdf
Ìjíròrò wa kìí ṣe lórí ìgbàgbọ́ tí a ní nínú ìsèjọba yìí nìkan.
00001-00250-99bbb30c
Gómìnà Ayọ̀dé fọkàn gbogbo àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ rẹ̀ balẹ̀ pé.
00001-00250-99bbb30c
Ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí pinnu láti fún àwọn ọ̀dọ́ ẹgbẹ̀rún méjì ní isẹ́.
00001-00250-99bbb30c
Wọn yóò ṣe àfilọ́lẹ̀ àwọn ètò ìrónilágbára fún àwọn ọ̀dọ́.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n tún se ìkọ̀lù sí ibi tí àwọn ikọ̀ ọlọ̀tẹ̀ ń sá pamọ́ sí.
05251-05500-PB050cdf
Ó sọ̀rọ̀ yìí nílùú Àbújá láti sọ nípa ìkọlù orí afẹ́fẹ́ ti ikọ̀ ọmọ ogun òfurufú.
05251-05500-PB050cdf
Ìjọba àpapọ̀ kò nilò láti yá owó nílẹ̀ òkèèrè.
00001-00250-99bbb30c
Tí ìjọba bá lè rí owó orí, wọn ò nílò láti yá owó mọ́.
00001-00250-99bbb30c
Ìyá àgbà sọ pé "ẹ ǹ lẹ́ níbẹ̀ yẹn".
00001-00250-99bbb30c
Ó wá kí alága àti ìgbìmọ̀ rẹ̀ kú orí ire fún ipò tuntun wọn.
00001-00250-99bbb30c
Ààrẹ pàṣẹ láti kọlu jàǹdùkú, ọ̀daràn àti olè lórí afẹ́fẹ́.
00001-00250-99bbb30c
Àárín gbùgbùn ìlú ni wọ́n fi ìpàdé àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹ̀gbẹ́ náà sí.
00001-00250-99bbb30c
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá náà.
00001-00250-99bbb30c
Ní ìbámu ìlànà yìí wọ́n pèsè ìrànwọ́ fún ikọ̀ ọmọ ogun òfurufú.
00001-00250-99bbb30c
Ààrẹ bá wọn kẹ́dùn lórí ìkọlù àti òfò ẹ̀mí tó ṣẹlẹ̀ nípínlẹ̀ náà.
00001-00250-99bbb30c
Ààrẹ fi dá wọn lójú pé orílẹ̀ èdè Nàíjíríà kò ní gbàgbé wọn.
00001-00250-99bbb30c
Amẹ́ríkà yóò ran Nàíjíríà lọ́wọ́ nípa ètò ajé, okòwò, ààbò àti ẹ̀kọ́.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n ṣe ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lórí ètò ìlera fún àǹfààní orílẹ̀ èdè méjéèjì.
00001-00250-99bbb30c
Bàbá náà sọ̀rọ̀ yìí níbi ayẹyẹ àádọ́rin ọdún tí wọń gba òmìnira.
00001-00250-99bbb30c
Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti pèsè ètò ìrànlọ́wọ́ fún Nàìjíríà.
00001-00250-99bbb30c
Adarí fún ọ̀rọ̀ òkèèrè ilẹ̀ Nàìjíríà tẹpẹlẹ mọ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ náà.
00001-00250-99bbb30c
Àyìndé máa ń parọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ kódà èṣù ò parọ́ tó o.
00001-00250-99bbb30c
Àjọṣe tó dán mọ́rán wà láàárín orílẹ̀-èdè méjèèjì.
00001-00250-99bbb30c
Àwọn àáfáà gbàdúrà fún àlàáfíà orílẹ̀-èdè Nàíjíríà.
00001-00250-99bbb30c
Ààrẹ Bùhárí lo àsìkò ayẹyẹ náà láti fi gbàdúrà fún tọkọ-taya.
00001-00250-99bbb30c
A mọ rírí rẹ̀ torí náà ni a ṣe ń jó tí à ń yọ̀.
00001-00250-99bbb30c
Nàìjíríà ti fẹnukò láti dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n padà sílẹ̀.
00001-00250-99bbb30c
Wọ́n dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórílẹ̀ èdè Ṣáínà padà sílé
00001-00250-99bbb30c
Ọlọ́run kò dà bí ènìyàn, ènìyàn aronipin.
00001-00250-99bbb30c
Àjọ ìdìbò yóò ríi dájú pé kò sí ìwà màgò-mágó ní ìgbà ìdìbò.
00001-00250-99bbb30c
Bírí-bírí layé ń yí bẹ́ẹ̀ ni àwa ẹ̀dá inú ẹ̀ ń yí pẹ̀lú.
00001-00250-99bbb30c
Adelé ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn.
00001-00250-99bbb30c
Ó rọ̀ wọ́n láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àjọ náà kí wọn lè ṣe àṣeyọrí.
00001-00250-99bbb30c
Ilé-ẹjọ́ gíga dá Kíkẹ́ láre gẹ́gẹ́ bi ó ṣe wà nínú ìwé òfin.
00001-00250-99bbb30c
Bí wọ́n ṣe ń paná ọ̀tẹ̀ kan ni òmíràn ń rú.
00001-00250-99bbb30c
Nínú ẹjọ́ tí adájọ́ dá ni ó ti sọ pé olùfẹ̀sùnkàn kò ní ẹ̀rí tó le.
00001-00250-99bbb30c
Ilé ẹjọ́ gíga da ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí wọn pè tako àṣeyọrí Ọbásànjọ́
00001-00250-99bbb30c
Ilé ẹjọ́ gíga ti gbà á gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò ọdùn yìí
00001-00250-99bbb30c
Adájọ́ náà dá ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí pé ẹjọ́ náà kò múnádóko tó.
00001-00250-99bbb30c
Àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu márùn-ún ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn da ẹjọ́ náà sígbó.
00001-00250-99bbb30c
Olùpẹ̀jọ́ náà kò ní ẹ̀rí tó múnádóko láti fi han àwọn ilé ẹjọ́ náà.
00001-00250-99bbb30c
Ilé-ẹjọ́ gíga dá Abíọ́lá láre nínú ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Èkó
00001-00250-99bbb30c
Ẹ jẹ́ ẹni tó ṣe é fọkàn tán àti ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà rere.
05251-05500-PB050cdf
Àti ẹni tó mọ̀ ọ́, àti ẹni tí ò mọ̀ ọ́ ni ó ń ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ.
00001-00250-99bbb30c
Oúnjẹ tí mo fẹ́ràn jùlọ ni èkuru àti ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ata díndín.
00001-00250-99bbb30c
Èèyàn gbọdọ̀ mọ ojúse rẹ̀ láti jẹ onítara àti láti má dáwọ́ lé wàhálà.
00001-00250-99bbb30c
Ìyàtọ̀ ńlá àti ìdàgbàsókè ló ti dé bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti bí ogún ọdún sẹ́yìn.
00001-00250-99bbb30c
Ìgbìmò àwọn aṣòfin ń ṣe ìpàdé ní inú ilé lọ́dọ̀ Ààrẹ
00001-00250-99bbb30c
Adébáyọ̀ jẹ́ àlejò pàtàkì níbi ayẹyẹ ọ̀hún náà àmọ́, kò wá.
00001-00250-99bbb30c
Ọkùnrin kì í ṣe ọkùnrin lásán, ẹni tó ní ọkàn akin ní í ṣe